Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Ayah by Ayah

Tags

Download Links

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni translation for Surah Al-Hujurat — Ayah 7

49:7
وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ فِيكُمۡ رَسُولَ ٱللَّهِۚ لَوۡ يُطِيعُكُمۡ فِي كَثِيرٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ لَعَنِتُّمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ حَبَّبَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَزَيَّنَهُۥ فِي قُلُوبِكُمۡ وَكَرَّهَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡكُفۡرَ وَٱلۡفُسُوقَ وَٱلۡعِصۡيَانَۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلرَّٰشِدُونَ ٧
Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín.1 Tí ó bá jẹ́ pé ó ń tẹ̀lé yín níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ (tó ń ṣẹlẹ̀) ni, dájúdájú ẹ̀yin ìbá ti kó ara yín sínú wàhálà. Ṣùgbọ́n Allāhu jẹ́ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ òdodo. Ó ṣe é ní ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ó sì jẹ́ kí ẹ kórira àìgbàgbọ́, ìwà burúkú àti ìyapa àṣẹ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùmọ̀nà.
Footnotes
  • [1] “Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín”, ìyẹn nígbà tí kò ì kú.