Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Ayah by Ayah

Tags

Download Links

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni translation for Surah Al-Hashr — Ayah 2

59:2
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن دِيَٰرِهِمۡ لِأَوَّلِ ٱلۡحَشۡرِۚ مَا ظَنَنتُمۡ أَن يَخۡرُجُواْۖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُم مَّانِعَتُهُمۡ حُصُونُهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَأَتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِنۡ حَيۡثُ لَمۡ يَحۡتَسِبُواْۖ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَۚ يُخۡرِبُونَ بُيُوتَهُم بِأَيۡدِيهِمۡ وَأَيۡدِي ٱلۡمُؤۡمِنِينَ فَٱعۡتَبِرُواْ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ ٢
Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítírà1 jáde kúrò nínú ilé wọn fún àkọ́kọ́ àkójọ (wọ́n sínú ìlú Ṣām). Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò ti lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran.
Footnotes
  • [1] Ìyẹn àwọn Yẹhudi ọmọ Nadīr.